Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 15:27-35 BIBELI MIMỌ (BM)

27. “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣẹ̀ láìmọ̀, yóo fi abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

28. Alufaa yóo ṣe ètùtù niwaju pẹpẹ fún olúwarẹ̀ tí ó ṣe àṣìṣe, a óo sì dáríjì í.

29. Òfin kan náà ni ó wà fún gbogbo àwọn tí o bá ṣẹ̀ láìmọ̀, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin ilẹ̀ Israẹli.

30. “Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́nmọ̀ ṣẹ̀, kò náání OLUWA, ìbáà ṣe ọmọ Israẹli tabi àjèjì tí ń gbé láàrin wọn, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀;

31. nítorí pé ó pẹ̀gàn ọ̀rọ̀ OLUWA, kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, a óo yọ ọ́ kúrò patapata, ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yóo sì wà lórí rẹ̀.”

32. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà ninu aṣálẹ̀, wọ́n rí ọkunrin kan tí ń ṣẹ́gi ní ọjọ́ ìsinmi;

33. àwọn tí wọ́n rí i mú un wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni ati gbogbo ìjọ eniyan.

34. Wọ́n fi sí àhámọ́ nítorí wọn kò tíì mọ ohun tí wọn yóo ṣe sí i.

35. OLUWA sọ fún Mose pé, “Pípa ni kí ẹ pa ọkunrin náà, kí gbogbo ìjọ eniyan sọ ọ́ lókùúta pa lẹ́yìn ibùdó.”

Ka pipe ipin Nọmba 15