Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 15:11-27 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe pẹlu akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan tabi àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọ̀dọ́ àgbò kọ̀ọ̀kan tabi ọmọ aguntan kọ̀ọ̀kan.

12. Ẹ óo mú àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wá pẹlu olukuluku ẹran tí ẹ bá fẹ́ fi rúbọ.

13. Nígbà tí àwọn ọmọ onílẹ̀ bá fẹ́ rú ẹbọ sísun, tí ó jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA, wọn óo tẹ̀lé ìlànà yìí.

14. Bí àjèjì kan tí ń gbé ààrin yín, tabi ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrin yín bá fẹ́ rú ẹbọ sísun, tí ó jẹ́ òórùn dídùn sí OLUWA, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo tẹ̀lé ìlànà tí mo fi lélẹ̀ fun yín, ìlànà yìí yóo wà fún ìrandíran yín.

15. Ìlànà kan náà ni yóo wà fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí wọ́n wà láàrin yín. Ìlànà yìí yóo wà títí lae ní ìrandíran yín. Bí ẹ ti rí níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ náà ni àjèjì tí ó wà láàrin yín rí.

16. Òfin ati ìlànà kan náà ni yóo wà fún ẹ̀yin ati àjèjì tí ń gbé pẹlu yín.”

17. OLUWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé,

18. Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mò ń mu yín lọ,

19. tí ẹ bá jẹ ninu oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ óo mú ọrẹ wá fún OLUWA.

20. Ẹ mú ọrẹ wá fún OLUWA lára àwọn àkàrà tí ẹ kọ́kọ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí ọrẹ láti ibi ìpakà.

21. Lára àwọn àkàrà tí ẹ bá kọ́kọ́ ṣe ni ẹ óo máa mú wá fi ṣe ọrẹ fún OLUWA ní ìrandíran yín.

22. “Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò pa àwọn òfin wọnyi, tí OLUWA fún Mose mọ́,

23. àní àwọn òfin tí OLUWA tipasẹ̀ Mose fún yín, láti ọjọ́ tí OLUWA ti fún un ní òfin títí lọ, ní ìrandíran yín;

24. bí gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá ṣẹ̀, láìmọ̀, wọn óo fi ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan rú ẹbọ sísun, olóòórùn dídùn sí OLUWA, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati ẹbọ ohun mímu, ati òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

25. Alufaa yóo ṣe ètùtù fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli, a óo sì dáríjì wọ́n nítorí pé àṣìṣe ni; wọ́n sì ti mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wá fún OLUWA nítorí àṣìṣe wọn.

26. A óo dáríjì gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ati àwọn àjèjì tí ń gbé ààrin wọn nítorí pé gbogbo wọn ni ó lọ́wọ́ sí àṣìṣe náà.

27. “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣẹ̀ láìmọ̀, yóo fi abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Nọmba 15