Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọmba 12:7-16 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ṣugbọn ti Mose, iranṣẹ mi yàtọ̀. Mo ti fi ṣe alákòóso àwọn eniyan mi.

8. Lojukooju ni èmi í máa bá a sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ ketekete sì ni, kì í ṣe àdììtú ọ̀rọ̀. Kódà, òun a máa rí ìrísí OLUWA. Kí ló dé tí ẹ kò fi bẹ̀rù ati sọ̀rọ̀ òdì sí i?”

9. Inú sì bí OLUWA sí àwọn mejeeji, ó sì kúrò lọ́dọ̀ wọn.

10. Bí ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ti gbéra sókè ni ẹ̀tẹ̀ bo Miriamu, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Nígbà tí Aaroni wo Miriamu ó ri wí pé ó ti di adẹ́tẹ̀.

11. Aaroni sì wí fún Mose pe, “Olúwa mi, jọ̀wọ́ má jẹ́ kí á jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà àìgbọ́n wa.

12. Má jẹ́ kí ó dàbí ọmọ tí ó ti kú kí á tó bí i, tí apákan ara rẹ̀ sì ti jẹrà.”

13. Mose ké pe Ọlọrun kí ó wò ó sàn.

14. OLUWA sì dáhùn pé, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ṣé ìtìjú rẹ̀ kò ha ní wà lára rẹ̀ fún ọjọ́ meje ni? Nítorí náà, jẹ́ kí wọ́n fi sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọ̀sẹ̀ kan, lẹ́yìn náà, kí wọ́n mú un pada.”

15. Wọ́n sì fi Miriamu sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ meje, àwọn eniyan náà kò sì kúrò níbẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n mú un pada.

16. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ni Haserotu, wọ́n sì pa àgọ́ wọn sí aṣálẹ̀ Parani.

Ka pipe ipin Nọmba 12