Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 9:19-30 BIBELI MIMỌ (BM)

19. nítorí àánú rẹ, o kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. Ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó ń tọ́ wọn sọ́nà kò fìgbà kan kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ́sàn-án, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀wọ̀n iná kò sì fi wọ́n sílẹ̀ lóru. Ó ń tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lálẹ́, láti máa tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa rìn.

20. O fún wọn ní ẹ̀mí rere rẹ láti máa kọ́ wọn, o kò dá mana rẹ dúró, o fi ń bọ́ wọn. O sì ń fún wọn ni omi mu nígbà tí òùngbẹ bá ń gbẹ wọ́n.

21. Ogoji ọdún ni o fi bọ́ wọn ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì ṣe àìní ohunkohun, aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ̀ wọn kò sì wú.

22. O gba ọpọlọpọ ìjọba ati ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè fún wọn, o sì fi ibi gbogbo fún wọn. Wọ́n gba ilẹ̀ ìní Sihoni, ọba Heṣiboni, ati ti Ogu, ọba Baṣani.

23. O jẹ́ kí ìrandíran wọn pọ̀ sí i bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, o sì kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba wọn pé wọn yóo lọ gbà.

24. Àwọn ọmọ wọn lọ sí ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á, o ṣẹgun àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, o sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́, àtàwọn, àtọba wọn, àtilẹ̀ wọn, kí àwọn ọmọ Israẹli lè ṣe wọ́n bí wọ́n bá ti fẹ́.

25. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo àwọn ìlú olódi ati ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú, wọ́n sì gba ilé tí ó kún fún ọpọlọpọ àwọn nǹkan dáradára, ati kànga, ọgbà àjàrà, igi olifi ati ọpọlọpọ igi eléso, nítorí náà wọ́n jẹ wọ́n yó, wọ́n sanra, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ninu oore ńlá rẹ.

26. “Ṣugbọn, wọ́n ṣe àìgbọràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Wọ́n pa àwọn òfin rẹ tì sí apákan, wọ́n pa àwọn wolii rẹ tí wọ́n ti ń kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n yipada sí ọ, wọ́n sì ń hùwà àbùkù sí ọ.

27. Nítorí náà, o fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá sì jẹ wọ́n níyà, nígbà tí ìyà ń jẹ wọ́n, wọ́n ké pè ọ́, o sì gbọ́ igbe wọn lọ́run, gẹ́gẹ́ bí àánú rẹ ńlá, o gbé àwọn kan dìde bíi olùgbàlà láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

28. Ṣugbọn lẹ́yìn tí wọ́n ti ní ìsinmi tán, wọ́n tún ṣe nǹkan burúkú níwájú rẹ, o sì tún fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn. Sibẹsibẹ, nígbà tí wọ́n ronupiwada tí wọ́n sì gbadura sí ọ, o gbọ́ lọ́run, lọpọlọpọ ìgbà ni o sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ.

29. Ò sì máa kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n lè yipada sí òfin rẹ. Sibẹ wọn a máa hùwà ìgbéraga, wọn kìí sìí pa òfin rẹ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọn a máa ṣẹ̀ sí òfin rẹ, tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá pamọ́, ẹni náà yóo yè. Ṣugbọn wọn ń dágunlá, wọ́n ń ṣe orí kunkun, wọn kò sì gbọ́ràn.

30. Ọpọlọpọ ọdún ni o fi mú sùúrù pẹlu wọ́n, tí o sì ń kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ Ẹ̀mí rẹ, láti ẹnu àwọn wolii rẹ, sibẹ wọn kò fetí sílẹ̀. Nítorí náà ni o ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń gbé ilẹ̀ náà ṣẹgun wọn.

Ka pipe ipin Nehemaya 9