Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:63-69 BIBELI MIMỌ (BM)

63. Bákan náà ni àwọn ọmọ alufaa wọnyi: àwọn ọmọ Hobaaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí wọ́n fẹ́ iyawo lára àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi, ṣugbọn tí wọn tún ń jẹ́ orúkọ àwọn àna wọn.)

64. Nígbà tí wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí wọn kò rí i, wọ́n yọ wọ́n kúrò lára àwọn alufaa, wọ́n sì kà wọ́n sí aláìmọ́.

65. Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fẹnu kan oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu yóo fi dé.

66. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ati ẹgbaa ó lé ojidinnirinwo (42,360),

67. yàtọ̀ sí àwọn iranṣẹkunrin wọn ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin lé ọọdunrun ati mẹtadinlogoji (7,337), wọ́n sì ní àwọn akọrin tí wọ́n jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245) lọkunrin ati lobinrin. Àwọn ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736),

68. àwọn ìbaaka wọn jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245),

69. àwọn ràkúnmí wọn jẹ́ ojilenirinwo ó dín marun-un (435), àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sì jẹ́ ẹgbaata ó lé ọrindinlẹgbẹrin (6,720).

Ka pipe ipin Nehemaya 7