Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:60-63 BIBELI MIMỌ (BM)

60. Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ ninu tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392).

61. Àwọn tí wọ́n wá láti Teli Mela, ati láti Teli Hariṣa, Kerubu, Adoni, ati Imeri, ṣugbọn tí wọn kò mọ ilé baba wọn tabi ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀, tí kò sì sí ẹ̀rí tí ó dájú, bóyá ọmọ Israẹli ni wọ́n tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí:

62. àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Wọ́n jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé meji (642).

63. Bákan náà ni àwọn ọmọ alufaa wọnyi: àwọn ọmọ Hobaaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí wọ́n fẹ́ iyawo lára àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi, ṣugbọn tí wọn tún ń jẹ́ orúkọ àwọn àna wọn.)

Ka pipe ipin Nehemaya 7