Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:6-14 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Orúkọ àwọn eniyan agbègbè náà, tí wọ́n pada ninu àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati Juda, tí olukuluku wọn sì pada sí ìlú rẹ̀ nìwọ̀nyí.

7. Wọ́n jọ dé pẹlu Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Asaraya, Raamaya, Nahamani, Modekai, Biliṣani, Misipereti, Bigifai, Nehumi, ati Baana.Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli nìyí:

8. Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa, ó lé mejilelaadọsan-an (2,172).

9. Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọrinlelọọdunrun ó dín mẹjọ (372).

10. Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652).

11. Àwọn ọmọ Pahati Moabu, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Jeṣua ati Joabu, jẹ́ ẹgbẹrinla ó lé mejidinlogun (2,818).

12. Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254).

13. Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ojilelẹgbẹrin ó lé marun-un (845).

14. Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ojidinlẹgbẹrin (760).

Ka pipe ipin Nehemaya 7