Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:55-65 BIBELI MIMỌ (BM)

55. àwọn ọmọ Barikosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema,

56. àwọn ọmọ Nesaya, ati àwọn ọmọ Hatifa.

57. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Sofereti, ati àwọn ọmọ Perida,

58. àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli,

59. àwọn ọmọ Ṣefataya, àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu, ati àwọn ọmọ Amoni.

60. Gbogbo àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ ninu tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392).

61. Àwọn tí wọ́n wá láti Teli Mela, ati láti Teli Hariṣa, Kerubu, Adoni, ati Imeri, ṣugbọn tí wọn kò mọ ilé baba wọn tabi ibi tí wọ́n ti ṣẹ̀, tí kò sì sí ẹ̀rí tí ó dájú, bóyá ọmọ Israẹli ni wọ́n tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí:

62. àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Wọ́n jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé meji (642).

63. Bákan náà ni àwọn ọmọ alufaa wọnyi: àwọn ọmọ Hobaaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí wọ́n fẹ́ iyawo lára àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi, ṣugbọn tí wọn tún ń jẹ́ orúkọ àwọn àna wọn.)

64. Nígbà tí wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí wọn kò rí i, wọ́n yọ wọ́n kúrò lára àwọn alufaa, wọ́n sì kà wọ́n sí aláìmọ́.

65. Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fẹnu kan oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu yóo fi dé.

Ka pipe ipin Nehemaya 7