Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:5-25 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Nígbà náà ni Ọlọrun fi sí mi lọ́kàn láti ranṣẹ pe àwọn ọlọ́lá jọ, ati àwọn olórí, ati àwọn eniyan yòókù, láti wá ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé tí wọ́n kọ orúkọ àwọn ìdílé tí wọ́n kọ́kọ́ wá sí, mo sì rí ohun tí wọ́n kọ sinu wọn pé:

6. Orúkọ àwọn eniyan agbègbè náà, tí wọ́n pada ninu àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati Juda, tí olukuluku wọn sì pada sí ìlú rẹ̀ nìwọ̀nyí.

7. Wọ́n jọ dé pẹlu Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Asaraya, Raamaya, Nahamani, Modekai, Biliṣani, Misipereti, Bigifai, Nehumi, ati Baana.Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli nìyí:

8. Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa, ó lé mejilelaadọsan-an (2,172).

9. Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọrinlelọọdunrun ó dín mẹjọ (372).

10. Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652).

11. Àwọn ọmọ Pahati Moabu, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Jeṣua ati Joabu, jẹ́ ẹgbẹrinla ó lé mejidinlogun (2,818).

12. Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254).

13. Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ojilelẹgbẹrin ó lé marun-un (845).

14. Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ojidinlẹgbẹrin (760).

15. Àwọn ọmọ Binui jẹ́ ojilelẹgbẹta ó lé mẹjọ (648).

16. Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbẹta lé mejidinlọgbọn (628).

17. Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbaa ó lé ọọdunrun ati mejilelogun (2,322).

18. Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ọtalelẹgbẹta ati meje (667).

19. Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹtadinlaadọrin (2,067).

20. Àwọn ọmọ Adini jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín marun-un (655).

21. Àwọn ọmọ Ateri tí wọn ń jẹ́ Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un.

22. Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ ọọdunrun ó lé mejidinlọgbọn (328).

23. Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹrinlelogun (324).

24. Àwọn ọmọ Harifi jẹ́ aadọfa ó lé meji (112).

25. Àwọn ọmọ Gibeoni jẹ́ marundinlọgọrun-un.

Ka pipe ipin Nehemaya 7