Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 7:4-8 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ìlú náà fẹ̀, ó sì tóbi, ṣugbọn àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ kéré níye, kò sì tíì sí ilé níbẹ̀.

5. Nígbà náà ni Ọlọrun fi sí mi lọ́kàn láti ranṣẹ pe àwọn ọlọ́lá jọ, ati àwọn olórí, ati àwọn eniyan yòókù, láti wá ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé tí wọ́n kọ orúkọ àwọn ìdílé tí wọ́n kọ́kọ́ wá sí, mo sì rí ohun tí wọ́n kọ sinu wọn pé:

6. Orúkọ àwọn eniyan agbègbè náà, tí wọ́n pada ninu àwọn tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati Juda, tí olukuluku wọn sì pada sí ìlú rẹ̀ nìwọ̀nyí.

7. Wọ́n jọ dé pẹlu Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Asaraya, Raamaya, Nahamani, Modekai, Biliṣani, Misipereti, Bigifai, Nehumi, ati Baana.Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli nìyí:

8. Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa, ó lé mejilelaadọsan-an (2,172).

Ka pipe ipin Nehemaya 7