Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 6:10-14 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ní ọjọ́ kan tí mo lọ sí ilé Ṣemaaya, ọmọ Delaaya, ọmọ Mehetabeli, tí wọ́n tì mọ́lé, ó ní “Jẹ́ kí á jọ pàdé ní ilé Ọlọrun ninu tẹmpili, nítorí wọ́n ń bọ̀ wá pa ọ́, alẹ́ ni wọ́n ó sì wá.”

11. Ṣugbọn mo dá a lóhùn pé, “Ṣé irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ? Àbí irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ sinu tẹmpili kí ó lọ máa gbé ibẹ̀? N kò ní lọ.”

12. Ó hàn sí mi pé kì í ṣe Ọlọrun ló rán an níṣẹ́ sí mi, ó kàn ríran èké sí mi ni, nítorí ti Tobaya ati Sanbalati tí wọ́n bẹ̀ ẹ́ lọ́wẹ̀.

13. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ lọ́wẹ̀ kí ó lè dẹ́rù bà mí, kí n lè ṣe bí ó ti wí, kí n dẹ́ṣẹ̀, kí wọ́n lè bà mí ní orúkọ jẹ́, kí wọ́n wá kẹ́gàn mi.

14. Áà, Ọlọrun mi, ranti ohun tí Tobaya ati Sanbalati ati Noadaya, wolii obinrin, ṣe sí mi, ati àwọn wolii yòókù tí wọ́n fẹ́ máa dẹ́rù bà mí.

Ka pipe ipin Nehemaya 6