Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 6:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí wọ́n sọ fún Sanbalati ati Tobaya ati Geṣemu ará Arabia ati àwọn ọ̀tá wa yòókù pé a ti tún odi náà mọ, ati pé kò sí àlàfo kankan mọ́ (lóòótọ́ n kò tíì ṣe ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè).

2. Sanbalati ati Geṣemu ranṣẹ sí mi, wọ́n ní “Wá, jẹ́ kí á pàdé ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.” Ṣugbọn wọ́n ti pète láti ṣe mí ní ibi.

3. Mo bá ranṣẹ pada sí wọn pé, mò ń ṣe iṣẹ́ pataki kan lọ́wọ́, kò ní jẹ́ kí n lè wá. Kò sì ní yẹ kí n dá iṣẹ́ náà dúró nítorí àtiwá rí wọn.

Ka pipe ipin Nehemaya 6