Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 3:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Eliaṣibu, Olórí alufaa, ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí àwọn náà jẹ́ alufaa bíi rẹ̀ múra, wọ́n sì kọ́ Ẹnubodè Aguntan. Wọ́n yà á sí mímọ́ wọn sì ṣe àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, wọ́n yà á sí mímọ́ títí dé Ilé Ìṣọ́ Ọgọrun-un, ati títí dé Ilé Ìṣọ́ Hananeli.

2. Ibẹ̀ ni àwọn ará Jẹriko ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Lẹ́yìn wọn ni Sakuri ọmọ Imiri bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó mọ abala tí ó tẹ̀lé e.

3. Àwọn ọmọ Hasenaa ni wọ́n kọ́ Ẹnubodè Ẹja, wọ́n ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà, wọ́n so àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, wọ́n sì ṣe ọ̀pá ìdábùú sí àwọn ìlẹ̀kùn náà.

4. Lẹ́yìn wọn ni Meremoti, ọmọ Uraya, ọmọ Hakosi ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn.Lẹ́yìn wọn, Meṣulamu ọmọ Berekaya, ọmọ Meṣesabeli náà ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ wọn.Lẹ́yìn wọn ni Sadoku, ọmọ Baana náà ṣe àtúnṣe abala tiwọn.

5. Lẹ́yìn wọn, àwọn ará Tekoa ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tiwọn, ṣugbọn àwọn ọlọ́lá ààrin wọn kò lọ́wọ́ sí iṣẹ́ àtúnṣe náà.

6. Joiada, ọmọ Pasea, ati Meṣulamu, ọmọ Besodeaya, ni wọ́n ṣe àtúnṣe Ẹnubodè Àtijọ́. Wọ́n ṣe ẹnu ọ̀nà, wọ́n ṣe àwọn ìlẹ̀kùn, wọ́n sì ṣe ọ̀pá ìdábùú sí wọn.

7. Lẹ́yìn wọn ni àwọn Melataya, ará Gibeoni, Jadoni, ará Meronoti, ati àwọn ará Gibeoni ati àwọn ará Misipa tí wọ́n wà ní abẹ́ ìjọba Ìkọjá Odò ṣe àtúnṣe abala ọ̀dọ̀ tiwọn.

8. Usieli ọmọ Hariaya alágbẹ̀dẹ wúrà ló ṣiṣẹ́ tẹ̀lé wọn.Lẹ́yìn wọn ni Hananaya, ọ̀kan ninu àwọn onítùràrí ṣe àtúnṣe ọ̀dọ̀ tirẹ̀, wọ́n sì ṣe é dé ibi Odi Gbígbòòrò.

9. Lẹ́yìn wọn ni Refaaya ọmọ Huri, aláṣẹ ìdajì agbègbè Jerusalẹmu ṣe àtúnṣe abala tí ó kàn.

10. Jedaaya ọmọ Harumafi ló ṣe àtúnṣe abala tí ó tẹ̀lé tiwọn, ó tún apá ibi tí ó kọjú sí ilé rẹ̀ ṣe.Lẹ́yìn wọn, Hatuṣi ọmọ Haṣabineya ṣe àtúnṣe tiwọn.

11. Malikija, ọmọ Harimu, ati Haṣubu, ọmọ Pahati Moabu, ṣe àtúnṣe apá ibòmíràn ati Ilé Ìṣọ́ ìléru.

Ka pipe ipin Nehemaya 3