Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 13:26-31 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ṣebí Solomoni ọba pàápàá dẹ́ṣẹ̀ nítorí ó fẹ́ irú àwọn obinrin bẹ́ẹ̀. Kò sí ọba tí ó dàbí rẹ̀ láàrin àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, Ọlọrun sì fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọrun sì fi jọba lórí gbogbo Israẹli, sibẹsibẹ, àwọn obinrin àjèjì ni wọ́n mú un dẹ́ṣẹ̀.

27. Ṣé a óo wá tẹ̀lé ìṣìnà yín, kí á sì máa ṣe irú nǹkan burúkú yìí, kí á sì máa fẹ́ àwọn obinrin àjèjì tí ó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọrun wa?”

28. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọkunrin Jehoiada, ọmọ Eliaṣibu olórí alufaa, fẹ́ ọmọ Sanbalati ará Horoni kan, nítorí náà mo lé e kúrò lọ́dọ̀ mi.

29. Ranti, Ọlọrun mi, nítorí pé wọ́n rú òfin àwọn alufaa, wọn kò sì mú ẹ̀jẹ́ àwọn alufaa ati ti àwọn ọmọ Lefi ṣẹ.

30. Nítorí náà mo wẹ̀ wọ́n mọ́ ninu gbogbo nǹkan àjèjì, mo sì fi ìdí iṣẹ́ wọn múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alufaa ati ọmọ Lefi. Olukuluku sì ní iṣẹ́ tí ó ń ṣe,

31. mo pèsè igi ìrúbọ, ní àkókò tí ó yẹ ati àwọn èso àkọ́so.Ranti mi sí rere, Ọlọrun mi.

Ka pipe ipin Nehemaya 13