Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nahumu 3:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Àwọn ẹlẹ́ṣin ti múra ìjàpẹlu idà ati ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà.Ọpọlọpọ ni wọ́n ti pa sílẹ̀,òkítì òkú kúnlẹ̀ lọ kítikìti;òkú sùn lọ bẹẹrẹ láìníye,àwọn eniyan sì ń kọlu àwọn òkúbí wọn tí ń lọ!

4. Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe,tí wọ́n fanimọ́ra,ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró,ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a;nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ,ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan.

5. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe,n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú;n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹojú yóo sì tì ọ́.

6. N óo mú ẹ̀gbin bá ọ n óo fi àbùkù kàn ọ́;n óo sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà ati ẹni àpéwò.

7. Ẹnu yóo ya gbogbo àwọn tí ó bá wò ọ́, wọn yóo máawí pé: ‘Ninefe ti di ahoro; ta ni yóo dárò rẹ̀?Níbo ni n óo ti rí olùtùnú fún ọ?’ ”

8. Ṣé ìwọ Ninefe sàn ju ìlú Tebesi lọ, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Naili, tí omi yíká, tí ó fi òkun ṣe ààbò, tí ó sì fi omi ṣe odi rẹ̀?

9. Etiopia ati Ijipti ni agbára rẹ̀ tí kò lópin; Puti ati Libia sì ni olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.

10. Sibẹsibẹ àwọn ọ̀tá kó o lọ sí ìgbèkùn, wọ́n ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní gbogbo àwọn ìkóríta wọn. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí àwọn ọlọ́lá ibẹ̀, wọ́n sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn eniyan pataki wọn.

11. Ninefe, ìwọ pàápàá yóo mu ọtí yó, o óo máa ta gbọ̀n- ọ́ngbọ̀n-ọ́n; o óo sì máa wá ààbò nítorí àwọn ọ̀tá rẹ.

12. Gbogbo ibi ààbò rẹ yóo dàbí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí àkọ́so èso rẹ̀ pọ́n bí wọn bá ti gbọ̀n ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni èso rẹ̀ yóo máa jábọ́ sí ẹnu ẹni tí yóo jẹ ẹ́.

13. Wò ó! Àwọn ọmọ ogun rẹ dàbí obinrin! Gbogbo ẹnubodè rẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ; iná sì ti jó gbogbo ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ.

14. Ẹ pọn omi sílẹ̀ de àkókò tí ogun yóo dótì yín, ẹ ṣe ibi ààbò yín kí ó lágbára; ẹ lọ sí ibi ilẹ̀ alámọ̀, ẹ gún amọ̀, kí ẹ fi ṣe bíríkì!

15. Ibẹ̀ ni iná yóo ti jó yín run, idà yóo pa yín lọ bí eṣú. Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ pọ̀ bí eṣú!

Ka pipe ipin Nahumu 3