Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nahumu 2:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ìlú Ninefe dàbí adágún odòtí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ.Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada.

9. Ẹ kó fadaka,ẹ kó wúrà!Ìlú náà kún fún ìṣúra,ati àwọn nǹkan olówó iyebíye.

10. A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro!Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú,orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,ìrora dé bá ọpọlọpọ,gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

11. Níbo ni ìlú tí ó dàbí ihò àwọn kinniun wà?Tí ó rí bí ibùgbé àwọn ọ̀dọ́ kinniun?Ibi tí kinniun ń gbé oúnjẹ rẹ̀ lọ,tí àwọn ọmọ rẹ̀ wà,tí kò sí ẹni tí ó lè dà wọ́n láàmú?

12. Akọ kinniun a máa fa ẹran yafún àwọn ọmọ rẹ̀,a sì máa lọ́ ẹran lọ́rùn pafún àwọn abo rẹ̀;a máa kó ẹran tí ó bá paati èyí tí ó fàya sinu ihò rẹ̀.

13. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.”

Ka pipe ipin Nahumu 2