Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mika 7:11-20 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ní ọjọ́ tí a óo bá mọ odi ìlú yín, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ọjọ́ náà ni a óo sún ààlà yín siwaju.

12. Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan yóo wá sọ́dọ̀ yín láti ilẹ̀ Asiria títí dé ilẹ̀ Ijipti, láti ilẹ̀ Ijipti títí dé bèbè odò Yufurate, láti òkun dé òkun, ati láti òkè ńlá dé òkè ńlá.

13. Ṣugbọn ayé yóo di ahoro nítorí ìwàkiwà àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀; àní nítorí iṣẹ́kíṣẹ́ ọwọ́ wọn.

14. OLUWA, fi ọ̀pá rẹ tọ́ àwọn eniyan rẹ, àní agbo aguntan ìní rẹ, tí wọn ń dá gbé ninu igbó, láàrin ilẹ̀ ọgbà; jẹ́ kí wọ́n máa jẹko ní Baṣani ati ní Gileadi bí ìgbà àtijọ́.

15. N óo fi ohun ìyanu hàn wọ́n gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

16. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo rí i, ojú agbára wọn yóo tì wọ́n; wọn óo pa ẹnu wọn mọ́; etí wọn óo sì di;

17. wọn óo fi ẹnu gbo ilẹ̀ bí ìgbín, pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì ni wọn yóo jáde bí ejò, láti ibi ààbò wọn; ninu ìbẹ̀rù, wọn óo pada tọ OLUWA Ọlọrun wá, ẹ̀rù rẹ yóo sì máa bà wọ́n.

18. Ta ló dàbí rẹ, Ọlọrun, tí ó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan, tí ó sì ń fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan ìní rẹ̀ yòókù, ibinu rẹ kì í wà títí lae, nítorí pé a máa dùn mọ́ ọ láti fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn.

19. O óo tún ṣàánú wa, o óo sì fẹsẹ̀ tẹ ẹ̀ṣẹ̀ wa ní àtẹ̀parẹ́. O óo sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa sí ìsàlẹ̀ òkun.

20. O óo fi òtítọ́ inú hàn sí Jakọbu, o óo sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún àwọn baba wa láti ìgbà àtijọ́.

Ka pipe ipin Mika 7