Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mika 6:3-16 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ọlọrun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, kí ni mo fi ṣe yín? Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi su yín? Ẹ dá mi lóhùn.

4. Èmi ni mo sá mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí mo rà yín pada kúrò lóko ẹrú; tí mo rán Mose, Aaroni ati Miriamu láti ṣáájú yín.

5. Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”

6. Kí ni n óo mú wá fún OLUWA, tí n óo fi rẹ ara mi sílẹ̀ níwájú Ọlọrun, ẹni gíga? Ṣé kí n wá siwaju rẹ̀ pẹlu ẹbọ sísun ni tabi pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù ọlọ́dún kan?

7. Ǹjẹ́ inú OLUWA yóo dùn bí mo bá mú ẹgbẹẹgbẹrun aguntan wá, pẹlu ẹgbẹgbaarun-un garawa òróró olifi? Ṣé kí n fi àkọ́bí mi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ mi, àní kí n fi ọmọ tí mo bí rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi?

8. A ti fi ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ?

9. Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará, ati àpéjọ gbogbo ìlú; ohun tí ó ti dára ni pé kí eniyan bẹ̀rù OLUWA;

10. Ǹjẹ́ mo lè gbàgbé ìṣúra aiṣododo tí ó wà ninu ilé àwọn eniyan burúkú, ati òṣùnwọ̀n èké ó jẹ́ ohun ìfibú?

11. Báwo ni mo ṣe lè dáríjì àwọn tí ń lo òṣùnwọ̀n èké; tí àpò wọn sì kún fún ìwọ̀n tí kò péye?

12. Àwọn ọlọ́rọ̀ yín kún fún ìwà ipá; òpùrọ́ ni gbogbo àwọn ará ìlú, ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì kún ẹnu wọn.

13. Nítorí náà, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí pa yín run n óo sọ ìlú yín di ahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

14. Ẹ óo jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó, ebi yóo sì túbọ̀ máa pa yín, ẹ óo kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kò ní dúró lọ́wọ́ yín, ogun ni yóo sì kó ohun tí ẹ kó jọ lọ.

15. Ẹ óo fúnrúgbìn, ṣugbọn ẹ kò ní kórè rẹ̀; ẹ óo ṣe òróró olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí i fi para; ẹ óo ṣe ọtí waini, ṣugbọn ẹ kò ní rí i mu.

16. Nítorí pé ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà ọba Omiri, ati ti ìdílé ọba Ahabu, ẹ sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn; kí n lè sọ ìlú yín di ahoro, kí àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ sì di ohun ẹ̀gàn; kí àwọn eniyan sì máa fi yín ṣẹ̀sín.

Ka pipe ipin Mika 6