Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mika 2:7-13 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ṣé irú ọ̀rọ̀ tí eniyan máa sọ nìyí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu? Ṣé OLUWA kò ní mú sùúrù mọ́ ni? Àbí ẹ rò pé òun ni ó ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi? Àbí ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe àwọn tí wọ́n bá ń rin ọ̀nà ẹ̀tọ́ ní rere?”

8. OLUWA ní: “Ṣugbọn ẹ dìde sí àwọn eniyan mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá, ẹ gba ẹ̀wù lọ́rùn àwọn tí wọn ń lọ lalaafia, àwọn tí wọn ń rékọjá lọ láìronú ogun.

9. Ẹ lé àwọn aya àwọn eniyan mi jáde kúrò ninu ilé tí wọ́n fẹ́ràn; ẹ sì gba ògo mi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn títí lae.

10. Ẹ dìde, ẹ máa lọ, nítorí pé ìhín yìí kì í ṣe ibi ìsinmi; nítorí pé ẹ ti hùwà ìríra tí ń mú ìparun ńlá báni.

11. “Wolii tí yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ati ẹ̀tàn ni àwọn eniyan wọnyi ń fẹ́, tí yóo sì máa waasu pé, ‘Ẹ óo ní ọpọlọpọ waini ati ọtí líle.’

12. “Dájúdájú, n óo kó gbogbo yín jọ, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, n óo kó àwọn ọmọ Israẹli yòókù jọ: n óo kó wọn pọ̀ bí aguntan, sinu agbo, àní bí agbo ẹran ninu pápá, ariwo yóo sì pọ̀ ninu agbo náà, nítorí ọ̀pọ̀ eniyan.”

13. Ọlọrun tíí ṣí ọ̀nà ni yóo ṣáájú wọn; wọn yóo já irin ẹnubodè, wọn yóo sì gba ibẹ̀ jáde. Ọba wọn ni yóo ṣáájú wọn, OLUWA ni yóo sì ṣiwaju gbogbo wọn.

Ka pipe ipin Mika 2