Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Malaki 2:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ó fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ́ni, kìí sọ̀rọ̀ àìtọ́. Ó bá mi rìn ní alaafia ati ìdúróṣinṣin, ó sì yí ọkàn ọpọlọpọ eniyan pada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀.

7. Láti ẹnu alufaa ni ó ti yẹ kí ìmọ̀ ti máa jáde, kí àwọn eniyan sì máa gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé, iranṣẹ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni.

8. “Ṣugbọn ẹ̀yin alufaa ti yapa kúrò ní ọ̀nà òtítọ́, ẹ ti mú ọ̀pọ̀ eniyan kọsẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ yín, ẹ sì ti da majẹmu tí mo bá Lefi dá.

9. Nítorí náà, n óo pa yín dà sí àìdára, ẹ óo sì di yẹpẹrẹ lójú àwọn eniyan; nítorí pé ẹ kò tẹ̀lé ìlànà mi, ẹ̀ ń fi ojuṣaaju bá àwọn eniyan lò nígbà tí ẹ bá ń kọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!”

10. Ṣebí baba kan náà ló bí wa? Ṣebí Ọlọrun kan náà ló dá wa? Kí ló dé tí a fi ń ṣe aiṣootọ sí ara wa, tí a sì ń sọ majẹmu àwọn baba wa di aláìmọ́?

11. Àwọn ará Juda jẹ́ alaiṣootọ sí OLUWA, àwọn eniyan ti ṣe ohun ìríra ní Israẹli ati ní Jerusalẹmu. Àwọn ará Juda ti sọ ibi mímọ́ tí OLUWA fẹ́ràn di aláìmọ́; àwọn ọmọkunrin wọn sì ti fẹ́ àjèjì obinrin, ní ìdílé abọ̀rìṣà.

12. Kí OLUWA yọ irú eniyan bẹ́ẹ̀ kúrò ní àwùjọ Jakọbu, kí ó má lè jẹ́rìí tabi kí ó dáhùn sí ohun tíí ṣe ti OLUWA, kí ó má sì lọ́wọ́ ninu ẹbọ rírú sí OLUWA àwọn ọmọ ogun mọ́ lae!

13. Ohun mìíràn tí ẹ tún ń ṣe nìyí. Ẹ̀ ń sọkún, omijé ojú yín ń ṣàn lára pẹpẹ OLUWA, ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ sì ń ké, nítorí pé OLUWA kò gba ọrẹ tí ẹ mú wá fún un.

14. Ẹ̀ ń bèèrè pé, “Kí ló dé tí kò fi gbà á?” Ìdí rẹ̀ ni pé, OLUWA ni ẹlẹ́rìí majẹmu tí ẹ dá pẹlu aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín, tí ẹ sì ṣe aiṣootọ sí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olùrànlọ́wọ́ yín ni, òun sì ni aya tí ẹ bá dá majẹmu.

15. Ṣebí ara kan náà ati ẹ̀jẹ̀ kan náà ni Ọlọrun ṣe ìwọ pẹlu rẹ̀? Kí ló dé tí Ọlọrun fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí rẹ̀ ni pé, Ọlọrun ń fẹ́ irú ọmọ tí yóo jẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ má ṣe hùwà aiṣootọ sí aya tí ẹ fẹ́ nígbà èwe yín.

Ka pipe ipin Malaki 2