Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Malaki 1:11-14 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nítorí pé, jákèjádò gbogbo ayé, láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ ni orúkọ mi ti tóbi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ibi gbogbo ni wọ́n sì ti ń sun turari sí mi, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ mímọ́ sí mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.

12. Ṣugbọn ẹ tàbùkù orúkọ mi nígbà tí ẹ sọ pé pẹpẹ OLUWA ti di àìmọ́, tí ẹ sì ń fi oúnjẹ tí ẹ pẹ̀gàn rúbọ lórí rẹ̀.

13. Ẹ̀ ń sọ pé, “Èyí sú wa!” Ẹ̀ ń yínmú sí mi. Ẹran tí ẹ fi ipá gbà, tabi èyí tí ó yarọ, tabi èyí tí ń ṣàìsàn ni ẹ̀ ń mú wá láti fi rúbọ. Ṣé ẹ rò pé n óo gba irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ yín?

14. Ègún ni fún arẹ́nijẹ; tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ akọ ẹran láti inú agbo rẹ̀, ṣugbọn tí ó fi ẹran tí ó ní àbùkù rúbọ sí OLUWA. Ọba ńlá ni mí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni wọ́n sì bẹ̀rù orúkọ mi.

Ka pipe ipin Malaki 1