Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 9:5-18 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Wọ́n mú àwọn ohun tí Mose paláṣẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ, gbogbo ìjọ eniyan sì dúró níwájú OLUWA.

6. Mose sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ fun yín láti ṣe nìyí, ògo OLUWA yóo hàn sí yín.”

7. Lẹ́yìn náà, Mose sọ fún Aaroni pé, “Súnmọ́ ibi pẹpẹ, kí o sì rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ati ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ ati fún àwọn eniyan náà. Gbé ẹbọ àwọn eniyan náà wá, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”

8. Aaroni bá súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó pa ọ̀dọ́ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀.

9. Àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá fún un, ó sì ti ìka bọ̀ ọ́, ó fi kan ara ìwo pẹpẹ, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ.

10. Ó mú ọ̀rá ọ̀dọ́ mààlúù náà, ati àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ kúrò ninu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.

11. Ó sì dáná sun ẹran ati awọ mààlúù náà lẹ́yìn ibùdó.

12. Ó pa ẹran ẹbọ sísun, àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì dà á sí ara pẹpẹ yípo.

13. Wọ́n gbé ẹran ẹbọ sísun tí wọ́n ti gé sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.

14. Ó fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun wọ́n papọ̀ pẹlu ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.

15. Lẹ́yìn náà ó fa ẹran ẹbọ sísun àwọn eniyan náà kalẹ̀, ó mú ewúrẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan náà, ó pa á, ó sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ti àkọ́kọ́.

16. Ó gbé ẹran ẹbọ sísun wá, ó sì fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

17. Ó gbé ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun ti òwúrọ̀.

18. Ó pa akọ mààlúù ati àgbò ẹbọ alaafia fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì dà á sórí pẹpẹ náà yípo.

Ka pipe ipin Lefitiku 9