Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 7:36-38 BIBELI MIMỌ (BM)

36. Ní ọjọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti máa fún wọn, ó jẹ́ ìpín tiwọn láti ìrandíran.”

37. Òfin ẹbọ sísun ni, ati ti ẹbọ ohun jíjẹ, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, ti ẹbọ ìyàsímímọ́, ati ti ẹbọ alaafia;

38. tí OLUWA paláṣẹ fún Mose, ní orí òkè Sinai ní ọjọ́ tí ó pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti mú ẹbọ wọn wá fún òun OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai.

Ka pipe ipin Lefitiku 7