Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 6:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “Pa á láṣẹ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ pé, èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ti ẹbọ sísun: ẹbọ sísun níláti wà lórí ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iná sì níláti máa jò lórí pẹpẹ náà ní gbogbo ìgbà.

10. Kí alufaa wọ ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ funfun rẹ̀, ati ṣòkòtò aṣọ funfun, kí ó kó eérú ẹbọ tí ó ti fi iná sun kúrò lórí pẹpẹ, kí ó sì dà á sí ibìkan.

11. Lẹ́yìn náà, kí ó bọ́ aṣọ iṣẹ́ alufaa rẹ̀ kí ó sì wọ aṣọ mìíràn, kí ó wá ru eérú náà jáde kúrò ninu àgọ́ sí ibi mímọ́ kan.

12. Kí iná orí pẹpẹ náà sì máa jó, kò gbọdọ̀ kú nígbà kan. Kí alufaa máa kó igi sí i ní àràárọ̀; kí ó máa to ẹbọ sísun lé e lórí, orí rẹ̀ ni yóo sì ti máa sun ọ̀rá ẹran tí ó bá fi rú ẹbọ alaafia.

13. Iná orí pẹpẹ náà gbọdọ̀ máa jó nígbà gbogbo, kò gbọdọ̀ kú.

14. “Èyí ni òfin tí ó jẹmọ́ ẹbọ ohun jíjẹ. Àwọn ọmọ Aaroni ni yóo máa rúbọ náà níwájú pẹpẹ, níwájú OLUWA.

15. Ọ̀kan ninu wọn yóo bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kan ninu ẹbọ ohun jíjẹ náà, pẹlu òróró ati turari tí ó wà lórí rẹ̀, yóo sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA ni.

16. Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóo jẹ ìyókù, láì fi ìwúkàrà sí i. Ibi mímọ́ kan ninu àgbàlá Àgọ́ Àjọ ni wọ́n ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

17. Wọn kò gbọdọ̀ fi ìwúkàrà sí i, bí wọ́n bá fi ṣe burẹdi, èmi ni mo fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn ninu ẹbọ sísun mi; ó jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ìmúkúrò ẹ̀bi.

Ka pipe ipin Lefitiku 6