Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 3:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; kí àwọn ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yípo.

9. Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá rẹ̀, gbogbo ọ̀rá tí ó wà ní ìrù rẹ̀ títí dé ibi egungun ẹ̀yìn rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo gbogbo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀,

10. kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí ati gbogbo ẹ̀dọ̀ rẹ̀.

11. Alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA.

12. “Bí ó bá jẹ́ pé ewúrẹ́ ni yóo fi rú ẹbọ náà, kí ó mú un wá siwaju OLUWA,

13. kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; àwọn ọmọ Aaroni yóo sì da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo.

14. Yóo sì yọ àwọn nǹkan wọnyi ninu rẹ̀ láti fi rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA: gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ọ̀rá tí ó bo ìfun rẹ̀,

15. kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀.

16. Kí alufaa sun wọ́n lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn. Ti OLUWA ni gbogbo ọ̀rá ẹran.

17. Kí èyí jẹ́ ìlànà ayérayé fún àtìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín, pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tabi ẹ̀jẹ̀.”

Ka pipe ipin Lefitiku 3