Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 27:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ó bá tó, yóo sì fi ìdámárùn-ún owó rẹ̀ lé e, ilẹ̀ náà yóo sì di tirẹ̀.

20. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ra ilẹ̀ náà pada, tabi ti ó bá ti ta ilẹ̀ náà fún ẹlòmíràn, kò ní ẹ̀tọ́ láti rà á pada mọ́.

21. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá jọ̀wọ́ ilẹ̀ náà ní ọdún Jubili, ó níláti jẹ́ mímọ́ fún OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí wọ́n ti fi fún OLUWA; yóo sì di ohun ìní alufaa.

22. “Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé rírà ni ó ra ilẹ̀ tí ó yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí kì í ṣe apá kan ninu ilẹ̀ àjogúnbá tirẹ̀,

23. alufaa yóo ṣírò iye tí ilẹ̀ náà bá tó títí di ọdún Jubili, ẹni náà yóo sì san iye rẹ̀ ní ọjọ́ náà bí ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA.

24. Nígbà tí ó bá di ọdún Jubili, ilẹ̀ yìí yóo pada di ti ẹni tí wọ́n rà á lọ́wọ́ rẹ̀, tí ilẹ̀ yìí jẹ́ ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́.

25. “Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ninu ibi mímọ́ ni kí ẹ máa lò láti wọn ohun gbogbo: Ogún ìwọ̀n gera ni yóo jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli kan.

26. “Ṣugbọn gbogbo ẹran tí ó bá ti jẹ́ àkọ́bí, ti OLUWA ni, ẹnikẹ́ni kò ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ní yà á sọ́tọ̀ mọ́; kì báà jẹ́ mààlúù tabi aguntan, ti OLUWA ni.

27. Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́, kí ó san owó rẹ̀ pada gẹ́gẹ́ bí iye tí ẹ bá dá lé e, kí ó sì fi ìdámárùn-ún owó náà lé e. Bí ẹni tí ó ni í kò bá sì rà á pada, kí wọ́n tà á ní iyekíye tí ẹ bá dá lé e.

28. “Ṣugbọn ohunkohun tí eniyan bá ti fi fún OLUWA, kì báà jẹ́ eniyan ni, tabi ẹranko, tabi ilẹ̀ àjogúnbá rẹ̀, yóo jẹ́ títà tabi kí ó rà á pada. Ohunkohun tí a bá ti fi fún OLUWA, ó di mímọ́ jùlọ fún OLUWA.

29. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá yà sọ́tọ̀ pé ó gbọdọ̀ jẹ́ pípa láàrin àwọn eniyan, ẹnìkan kò gbọdọ̀ rà á pada, pípa ni wọ́n gbọdọ̀ pa á.

30. “Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà, kì báà jẹ́ ti èso ilẹ̀, tabi ti èso igi, ti OLUWA ni; mímọ́ ni fún OLUWA.

31. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá rẹ̀ pada, ó níláti fi ìdámárùn-ún ìdámẹ́wàá yìí lé e.

Ka pipe ipin Lefitiku 27