Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 26:23-43 BIBELI MIMỌ (BM)

23. “Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ ba kọ̀, ti ẹ kò yipada, ṣugbọn tí ẹ kẹ̀yìn sí mi,

24. èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn si yín, n óo sì jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.

25. N óo fi ogun ko yín, tí yóo gbẹ̀san nítorí majẹmu mi. Bí ẹ bá sì kó ara yín jọ sinu àwọn ìlú olódi yín, n óo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin yín, n óo sì fi yín lé àwọn ọ̀tá yín lọ́wọ́.

26. Nígbà tí mo bá gba oúnjẹ lẹ́nu yín, obinrin mẹ́wàá ni yóo máa jókòó nídìí ẹyọ ààrò kan ṣoṣo láti ṣe burẹdi. Wíwọ̀n ni wọn yóo máa wọn oúnjẹ le yín lọ́wọ́; ẹ óo jẹ, ṣugbọn ẹ kò ní yó.

27. “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, ṣugbọn tí ẹ tún kẹ̀yìn sí mi,

28. n óo fi ibinu kẹ̀yìn sí yín, n óo sì jẹ yín níyà fúnra mi, nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.

29. Ebi yóo pa yín tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ óo máa pa àwọn ọmọ yín jẹ.

30. N óo wó àwọn ilé ìsìn yín gbogbo tí wọ́n wà lórí òkè, n óo wó àwọn pẹpẹ turari yín lulẹ̀; n óo kó òkú yín dà sórí àwọn oriṣa yín, ọkàn mi yóo sì kórìíra yín.

31. N óo sọ àwọn ìlú yín di ahoro, àwọn ilé ìsìn yín yóo sì ṣófo, n kò ní gba ẹbọ yín mọ́.

32. N óo run ilẹ̀ yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu yóo fi ya àwọn ọ̀tá yín, tí wọn yóo pada wá tẹ̀dó ninu rẹ̀.

33. N óo fọ́n yín káàkiri ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, idà ni wọn yóo máa fi pa yín ní ìpakúpa, ilẹ̀ yín ati àwọn ìlú yín yóo di ahoro.

34. Nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, ilẹ̀ ti ẹ̀yin pàápàá yóo wá ní ìsinmi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà ní ahoro, ilẹ̀ yín yóo gbádùn ìsinmi rẹ̀.

35. Nígbà tí ó bá wà ní ahoro, yóo ní irú ìsinmi tí kò ní rí ni àkókò ìsinmi yín, nígbà tí ẹ̀ ń gbé inú rẹ̀.

36. “Ìwọ̀nba àwọn tí wọ́n bá kù, n óo da jìnnìjìnnì bo ọkàn wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, tóbẹ́ẹ̀ tí ìró ewé tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lásán yóo máa lé wọn sá; wọn yóo sì máa sá àsá-dojúbolẹ̀ bí ẹni pé ogun ní ń lé wọn. Wọn yóo máa ṣubú nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn.

37. Wọn yóo máa ṣubú lórí ara wọn bí ẹni tí ogun ń lé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń lé wọn. Kò sì ní sí agbára fun yín láti dúró níwájú àwọn ọ̀tá yín.

38. Ẹ óo parun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóo sì gbé yín mì.

39. Ìwọ̀nba ẹ̀yin tí ẹ bá ṣẹ́kù, kíkú ni ẹ óo máa kú sára lórí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín, nítorí àìdára yín ati ti àwọn baba yín.

40. “Ṣugbọn bí wọn bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wọn, nípa ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí wọ́n hù sí mi, ati lílòdì tí wọ́n lòdì sí mi,

41. tí mo fi kẹ̀yìn sí wọn, tí mo fi mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; bí ọkàn wọn tí ó ti yigbì tẹ́lẹ̀ bá rọ̀, tí wọ́n bá sì ṣe àtúnṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn,

42. n óo ranti majẹmu tí mo bá Jakọbu, ati Isaaki, ati Abrahamu dá, n óo sì ranti ilẹ̀ náà.

43. Ṣugbọn wọn yóo jáde kúrò ninu ilẹ̀ náà, ilẹ̀ náà yóo sì ní ìsinmi nígbà ti ó bá wà ní ahoro, nígbà tí wọn kò bá sí níbẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ gba ìjẹníyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé, wọ́n kẹ́gàn ìdájọ́ mi, wọ́n sì kórìíra ìlànà mi.

Ka pipe ipin Lefitiku 26