Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 25:38-52 BIBELI MIMỌ (BM)

38. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ó mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi ilẹ̀ Kenaani fún ọ ati láti jẹ́ Ọlọrun rẹ.

39. “Bí arakunrin rẹ, tí ń gbé tòsí rẹ bá di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún ọ, o kò gbọdọ̀ mú un sìn bí ẹrú.

40. Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tabi bí àlejò; kí ó máa ṣiṣẹ́ fún ọ títí di ọdún jubili.

41. Nígbà náà ni yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ati sórí ilẹ̀ ìní àwọn baba rẹ̀.

42. Nítorí pé, iranṣẹ mi ni wọ́n, tí mo kó jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹnìkan kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú.

43. O kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ.

44. Láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí yín ká ni ẹ ti lè ra ẹrukunrin tabi ẹrubinrin.

45. Ẹ sì lè rà láàrin àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín ati àwọn ìdílé wọn tí wọ́n wà pẹlu yín, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ yín, wọ́n lè di tiyín.

46. Ẹ lè fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín nígbà tí ẹ bá kú, kí wọn lè jogún wọn títí lae. Wọ́n lè di ẹrú yín, ṣugbọn ẹ̀yin ọmọ Israẹli tí ẹ jẹ́ arakunrin ara yín, ẹ kò gbọdọ̀ mú ara yín sìn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú ara yín.

47. “Bí àlejò tí ó wà láàrin yín bá di ọlọ́rọ̀ tí arakunrin rẹ̀ tí ó jẹ́ aládùúgbò rẹ̀ sì di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún àlejò náà, tabi fún ọ̀kan ninu ìdílé àlejò yín,

48. lẹ́yìn tí ó bá ti ta ara rẹ̀, wọ́n lè rà á pada: ọ̀kan ninu àwọn arakunrin rẹ̀ lè rà á pada.

49. Arakunrin baba tabi ìyá rẹ̀, tabi ọ̀kan ninu àwọn ìbátan rẹ̀ tabi ẹnìkan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ le rà á pada. Bí òun pàápàá bá sì di ọlọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ pada.

50. Kí òun ati ẹni tí ó rà á jọ ṣírò iye ọdún tí ó fi ta ara rẹ̀, láti ọdún tí ó ti ta ara rẹ̀ fún un títí di ọdún jubili. Iye ọdún tí ó bá kù ni wọn yóo fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀. Wọn yóo ṣírò àkókò tí ó ti lò lọ́dọ̀ olówó rẹ̀ bí àkókò tí alágbàṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

51. Bí iye ọdún tí ó kù bá pọ̀, yóo ṣírò iye tí owó ìràpadà rẹ̀ kù ninu iye tí wọ́n san lórí rẹ̀, yóo sì san án pada.

52. Bí ọdún tí ó kù tí ọdún jubili yóo fi pé kò bá pọ̀ mọ́, wọn yóo jọ ṣírò iye ọdún tí ó kù fún un láti fi sìn ín, òun ni yóo sì fi ṣírò owó ìràpadà rẹ̀ tí ó kù tí yóo san.

Ka pipe ipin Lefitiku 25