Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 25:33-45 BIBELI MIMỌ (BM)

33. Ṣugbọn bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi kò bá lo ẹ̀tọ́ ìràpadà yìí, ẹni tí ó bá ra ilé náà lọ́wọ́ rẹ̀ ninu ìlú olódi, yóo jọ̀wọ́ ilé náà sílẹ̀ ní ọdún jubili, nítorí pé, àwọn ilé tí ó wà ní ìlú àwọn ọmọ Lefi jẹ́ ìní tiwọn láàrin àwọn eniyan Israẹli.

34. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò, tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú wọn, nítorí pé, ogún tiwọn nìyí títí ayérayé.

35. “Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè bọ́ ara rẹ̀ mọ́, o níláti máa bọ́ ọ, kí ó sì máa gbé ọ̀dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àlejò ati àjèjì.

36. O kò gbọdọ̀ gba èlé lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ, kí o sì jẹ́ kí arakunrin rẹ máa bá ọ gbé.

37. O kò gbọdọ̀ yá a ní owó kí o gba èlé, o kò sì gbọdọ̀ fún un ní oúnjẹ kí o gba èrè.

38. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ó mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi ilẹ̀ Kenaani fún ọ ati láti jẹ́ Ọlọrun rẹ.

39. “Bí arakunrin rẹ, tí ń gbé tòsí rẹ bá di aláìní, tí ó sì ta ara rẹ̀ fún ọ, o kò gbọdọ̀ mú un sìn bí ẹrú.

40. Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tabi bí àlejò; kí ó máa ṣiṣẹ́ fún ọ títí di ọdún jubili.

41. Nígbà náà ni yóo kúrò lọ́dọ̀ rẹ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, yóo pada sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, ati sórí ilẹ̀ ìní àwọn baba rẹ̀.

42. Nítorí pé, iranṣẹ mi ni wọ́n, tí mo kó jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹnìkan kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú.

43. O kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ líle mú un, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ.

44. Láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yí yín ká ni ẹ ti lè ra ẹrukunrin tabi ẹrubinrin.

45. Ẹ sì lè rà láàrin àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín ati àwọn ìdílé wọn tí wọ́n wà pẹlu yín, tí wọ́n bí ní ilẹ̀ yín, wọ́n lè di tiyín.

Ka pipe ipin Lefitiku 25