Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 24:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. “Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

15. Wí fún àwọn eniyan Israẹli pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé Ọlọrun rẹ̀ yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ nítorí rẹ̀.

16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á. Gbogbo ìjọ eniyan yóo sọ ọ́ ní òkúta pa, kì báà jẹ́ àlejò, kì báà jẹ́ onílé; tí ó bá ṣá ti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á.

17. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa eniyan, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹran ẹlẹ́ran, yóo san án pada. Ohun tí ẹ̀tọ́ wí ni pé, kí á fi ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.

19. “Bí ẹnìkan bá ṣá aládùúgbò rẹ̀ lọ́gbẹ́, irú ọgbẹ́ tí ó ṣá aládùúgbò rẹ̀ gan-an ni wọn yóo ṣá òun náà. Bí ẹnìkan bá ṣe aládùúgbò rẹ̀ léṣe, tí ó sì di ohun àbùkù sí i lára, ohun tí ó ṣe sí aládùúgbò rẹ̀ ni kí wọ́n ṣe sí òun náà.

20. Bí ó bá dá egungun aládùúgbò rẹ̀, kí wọ́n dá egungun tirẹ̀ náà, bí ó bá fọ́ ọ lójú, kí wọ́n fọ́ ojú tirẹ̀ náà, bí ó bá yọ eyín rẹ̀, kí wọ́n yọ eyín tirẹ̀ náà; irú ohun tí ó bá fi ṣe ẹlòmíràn gan-an ni kí wọn fi ṣe òun náà.

21. Ẹni tí ó bá pa ẹran, yóo san òmíràn pada, ẹni tí ó bá sì pa eniyan, wọn yóo pa òun náà.

22. Òfin kan náà tí ó de àlejò, ni ó gbọdọ̀ de onílé, nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

23. Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Wọ́n mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

Ka pipe ipin Lefitiku 24