Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 24:10-17 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ọkunrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli, ṣugbọn tí baba rẹ̀ jẹ́ ará Ijipti. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó bá àwọn ọmọ Israẹli jáde, ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin òun ati ọkunrin kan, tí ó jẹ́ ọmọ Israẹli, ní ibùdó.

11. Ọkunrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli yìí bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, bí ó ti ń búra ni ó ń ṣépè. Wọ́n bá mú un tọ Mose wá; orúkọ ìyá ọmọkunrin náà ni Ṣelomiti ọmọ Dibiri láti inú ẹ̀yà Dani.

12. Wọ́n tì í mọ́lé títí tí wọn fi mọ ohun tí OLUWA fẹ́ kí wọ́n ṣe sí i.

13. OLUWA sọ fún Mose pé,

14. “Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

15. Wí fún àwọn eniyan Israẹli pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé Ọlọrun rẹ̀ yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ nítorí rẹ̀.

16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á. Gbogbo ìjọ eniyan yóo sọ ọ́ ní òkúta pa, kì báà jẹ́ àlejò, kì báà jẹ́ onílé; tí ó bá ṣá ti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á.

17. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa eniyan, pípa ni wọn yóo pa òun náà.

Ka pipe ipin Lefitiku 24