Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 23:20-25 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Alufaa yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, pẹlu burẹdi tí ẹ fi àkọ́so ọkà ṣe, ati àgbò meji náà, wọn yóo jẹ́ ọrẹ mímọ́ fún OLUWA, tí a óo yà sọ́tọ̀ fún àwọn alufaa.

21. Ẹ pe àpèjẹ mímọ́ ní ọjọ́ náà; ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kankan ní ọjọ́ náà. Ìlànà ni èyí yóo jẹ́ fún arọmọdọmọ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín títí lae.

22. “Nígbà tí ẹ bá ń kórè oko yín, ẹ kò gbọdọ̀ kórè títí dé ààlà patapata. Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè tán, ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ tún kórè àwọn èso tí ẹ bá gbàgbé. Ẹ gbọdọ̀ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn talaka ati àwọn àlejò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

23. OLUWA sọ fun Mose

24. pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ ya ọjọ́ kinni oṣù keje sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀. Yóo jẹ́ ọjọ́ ìrántí, ẹ óo kéde rẹ̀ pẹlu ìró fèrè, ẹ óo sì ní àpèjọ mímọ́.

25. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ líle kan, ẹ sì níláti rú ẹbọ sísun sí OLUWA.”

Ka pipe ipin Lefitiku 23