Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 22:29-33 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Nígbà tí ẹ bá sì ń rú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA, ẹ gbọdọ̀ rú u ní ọ̀nà tí yóo fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà.

30. Ẹ níláti jẹ gbogbo rẹ̀ tán ní ọjọ́ kan náà, kò gbọdọ̀ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Èmi ni OLUWA.

31. “Ẹ gbọdọ̀ ṣàkíyèsí òfin mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́. Èmi ni OLUWA.

32. Ẹ kò gbọdọ̀ ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́, ẹ gbọdọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún mi láàrin gbogbo eniyan Israẹli. Èmi ni OLUWA tí mo sọ yín di mímọ́,

33. tí mo sì ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti máa jẹ́ Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Lefitiku 22