Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 19:28-37 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Ẹ kò gbọdọ̀ ya ara yín lábẹ nítorí òkú, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fín ara yín rárá. Èmi ni OLUWA.

29. “Ẹ kò gbọdọ̀ ba ọmọbinrin yín jẹ́, nípa fífi ṣe aṣẹ́wó; kí ilẹ̀ náà má baà di ilẹ̀ àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà burúkú.

30. Ẹ gbọdọ̀ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ wọ ilé mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA.

31. “Ẹ kò gbọdọ̀ kó ọ̀rọ̀ yín lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláyẹ̀wò tabi àwọn abókùúsọ̀rọ̀, kí wọ́n má baà sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni OLUWA.

32. “Ẹ máa bu ọlá fún àwọn ogbó, kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà; kí ẹ sì máa bẹ̀rù Ọlọrun yín. Èmi ni OLUWA.

33. “Nígbà tí àlejò kan bá wọ̀ tì yín ninu ilẹ̀ yín, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi.

34. Bí ẹ ti ń ṣe sí ọmọ onílé ni kí ẹ máa ṣe sí àlejò tí ó wọ̀ sọ́dọ̀ yín, ẹ fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara yín, nítorí pé ẹ̀yin pàápàá ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.

35. “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣèrú nígbà tí ẹ bá ń wọn nǹkan fún eniyan, kì báà jẹ́ ohun tí a fi ọ̀pá wọ̀n, tabi ohun tí a fi òṣùnwọ̀n wọ̀n, tabi ohun tí a kà,

36. òṣùnwọ̀n yín gbọdọ̀ péye: ìwọ̀n efa tí ó péye ati ìwọ̀n hini tí ó péye ni ẹ gbọdọ̀ máa lò. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó kó yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti wá.

37. Ẹ gbọdọ̀ máa pa gbogbo ìlànà mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo òfin mi. Èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Lefitiku 19