Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 18:22-30 BIBELI MIMỌ (BM)

22. O kò gbọdọ̀ bá ọkunrin lòpọ̀ gẹ́gẹ́ bí obinrin, ohun ìríra ni.

23. O kò sì gbọdọ̀ bá ẹranko lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni obinrin kò sì gbọdọ̀ fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹranko láti bá a lòpọ̀; ìwà burúkú ni.

24. “Má ṣe fi èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí a dárúkọ wọnyi ba ara rẹ jẹ́, nítorí pé, nǹkan wọnyi ni àwọn orílẹ̀-èdè tí mò ń lé jáde kúrò níwájú yín fi ba ara wọn jẹ́.

25. Ilẹ̀ náà di ìbàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà sì ń ti àwọn eniyan inú rẹ̀ jáde.

26. Ẹ gbọdọ̀ pa àwọn ìlànà, ati àwọn òfin mi wọnyi mọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyíkéyìí ninu àwọn ohun ìríra wọnyi, kì báà jẹ́ onílé ninu yín, tabi àlejò tí ń ṣe àtìpó láàrin yín.

27. Nítorí pé gbogbo àwọn ohun ìríra wọnyi ni àwọn tí wọ́n ti gbé ilẹ̀ náà ṣáájú yín ti ṣe, tí wọ́n sì fi ba ilẹ̀ náà jẹ́.

28. Kí ilẹ̀ náà má baà ti ẹ̀yin náà jáde nígbà tí ẹ bá bà á jẹ́, bí ó ti ti àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ ṣáájú yín jáde.

29. Nítorí pé, a óo yọ àwọn tí wọ́n bá ṣe àwọn ohun ìríra kúrò láàrin àwọn eniyan wọn.

30. “Nítorí náà, ẹ pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ má sì ṣe èyíkéyìí ninu àwọn ohun ìríra wọnyi, tí àwọn tí wọ́n ṣáájú yín ṣe, kí ẹ má fi wọ́n ba ara yín jẹ́. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.”

Ka pipe ipin Lefitiku 18