Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 15:2-13 BIBELI MIMỌ (BM)

2. sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Nígbà tí nǹkan bá dà jáde lára ọkunrin, nǹkan tí ó jáde lára rẹ̀ yìí jẹ́ aláìmọ́.

3. Èyí sì ni òfin tí ó jẹmọ́ àìmọ́ rẹ̀, nítorí nǹkan tí ó ti ara rẹ̀ jáde; kì báà jẹ́ pé ó ń dà lọ́wọ́ lọ́wọ́, tabi ó ti dà tán, nǹkan tí ó dà yìí jẹ́ àìmọ́ lára rẹ̀.

4. Ibùsùn tí ẹni náà bá dùbúlẹ̀ lé lórí di aláìmọ́, ohunkohun tí ó bá sì fi jókòó di aláìmọ́ pẹlu.

5. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkohun tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi jókòó, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

7. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ẹni náà, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

8. Bí ẹnikẹ́ni tí nǹkan dà lára rẹ̀ bá tutọ́ sí ara ẹni tí ó mọ́, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

9. Gàárì ẹṣin tí ẹni tí nǹkan bá dà lára rẹ̀ bá fi gun ẹṣin di aláìmọ́.

10. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kan ohunkohun, ninu ohun tí ó fi jókòó di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ru èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan tí ẹni náà fi jókòó, fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀; olúwarẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

11. Ẹni tí nǹkan ọkunrin dà lára rẹ̀ yìí gbọdọ̀ fọ ọwọ́ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ẹni náà bá fi ọwọ́ kàn, kí ó tó fọ ọwọ́ rẹ̀, olúwarẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

12. Kí wọ́n fọ́ kòkò tí ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí bá fi ọwọ́ kàn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ohun èlò onígi tí ó bá fọwọ́ kàn, wọ́n gbọdọ̀ fọ̀ wọn.

13. “Nígbà tí wọ́n bá sọ ẹni tí nǹkan dà lára rẹ̀ yìí di mímọ́ kúrò ninu ohun tí ó dà lára rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ meje fún ìwẹ̀nùmọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ ninu odò tí ó ń ṣàn; yóo sì di mímọ́.

Ka pipe ipin Lefitiku 15