Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 14:11-25 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Alufaa tí ó ṣe ètò ìwẹ̀nùmọ́ ẹni náà yóo mú adẹ́tẹ̀ náà ati àwọn nǹkan ìwẹ̀nùmọ́ wá siwaju OLUWA lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

12. Lẹ́yìn náà, yóo mú ọ̀kan ninu àwọn ọ̀dọ́ àgbò náà, yóo fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan, yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

13. Alufaa náà yóo pa àgbò náà níbi tí wọ́n ti máa ń pa ẹran fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ti ẹbọ sísun ninu ibi mímọ́, nítorí pé ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi jẹ́ ti alufaa, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ohun mímọ́ patapata ni.

14. Alufaa yóo mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi yìí, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ wẹ̀ mọ́.

15. Alufaa yóo mú ninu ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì rẹ̀.

16. Yóo ti ìka ọ̀tún rẹ̀ bọ òróró tí ó wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo sì fi ìka rẹ̀ wọ́n òróró náà níwájú OLUWA ní ìgbà meje.

17. Alufaa yóo mú ninu òróró tí ó kù ní ọwọ́ òsì rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀, tí ó ti kọ́ fi ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi kàn.

18. Alufaa yóo fi òróró tí ó kù ní ọwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́. Lẹ́yìn náà, yóo ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA.

19. “Alufaa yóo rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́, lẹ́yìn náà, yóo pa ẹran ẹbọ sísun náà.

20. Alufaa yóo rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ lórí pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ni alufaa yóo ṣe ṣe ètùtù fún un, tí yóo sì di mímọ́.

21. “Ṣugbọn bí adẹ́tẹ̀ náà bá talaka tóbẹ́ẹ̀ tí apá rẹ̀ kò ká àwọn nǹkan tí a kà sílẹ̀ wọnyi, ó lè mú àgbò kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí alufaa yóo fì, láti fi ṣe ètùtù fún un. Kí ó sì tún mú ìdámẹ́wàá ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kan tí ó kúnná dáradára, tí wọ́n fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ, pẹlu ìwọ̀n ìgò òróró kan,

22. ati àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, èyíkéyìí tí apá rẹ̀ bá ká. Wọn yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, wọn yóo sì fi ekeji rú ẹbọ sísun.

23. Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo kó wọn tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, níwájú OLUWA fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀.

24. Alufaa yóo mú àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi ati ìwọ̀n ìgò òróró náà, yóo fì wọ́n bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA.

25. Yóo pa àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, yóo sì mú díẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, yóo fi kan ṣóńṣó etí ọ̀tún ẹni tí wọ́n fẹ́ sọ di mímọ́ ati àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

Ka pipe ipin Lefitiku 14