Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 13:31-40 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Bí alufaa bá yẹ àrùn ẹ̀yi yìí wò, tí kò bá jìn ju awọ ara lọ, tí irun dúdú kò sì hù jáde ninu rẹ̀, kí alufaa ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje.

32. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ ẹni náà wò. Bí ẹ̀yi náà kò bá tàn káàkiri, tí irun ibẹ̀ kò sì pọ́n, tí ẹ̀yi náà kò sì jìn ju awọ ara rẹ̀ lọ,

33. kí ó fá irun orí tabi ti àgbọ̀n olúwarẹ̀, ṣugbọn kí ó má fá irun ọ̀gangan ibi tí ẹ̀yi náà wà. Kí alufaa tún ti ẹni náà mọ́lé fún ọjọ́ meje sí i.

34. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ keje, kí alufaa yẹ àrùn ẹ̀yi náà wò, tí àrùn náà kò bá tàn káàkiri sí i, tí kò sì jìn ju awọ ara lọ, kí alufaa pè é ní mímọ́, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì di mímọ́.

35. Ṣugbọn bí àrùn ẹ̀yi yìí bá bẹ̀rẹ̀ sí i tàn káàkiri lẹ́yìn ìwẹ̀nùmọ́,

36. kí alufaa tún yẹ̀ ẹ́ wò, bí ẹ̀yi náà bá ti gbilẹ̀ lára rẹ̀, kí alufaa má wulẹ̀ wò bóyá irun rẹ̀ pọ́n tabi kò pọ́n mọ́, aláìmọ́ ni.

37. Ṣugbọn bí ẹ̀yi yìí bá ti dáwọ́ dúró, tí irun dúdú ti bẹ̀rẹ̀ sí hù ní ọ̀gangan ibẹ̀, ẹ̀yi náà ti san, ẹni náà sì ti di mímọ́. Kí alufaa pè é ní mímọ́.

38. “Bí ibìkan lára ọkunrin tabi obinrin bá déédé ṣẹ́ funfun,

39. kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ọ̀gangan ibẹ̀ bá funfun díẹ̀ tí ó dúdú díẹ̀, ara olúwarẹ̀ kàn fín lásán ni, ó mọ́.

40. “Bí irun orí ọkunrin bá re, orí rẹ̀ pá ni, ṣugbọn ó mọ́.

Ka pipe ipin Lefitiku 13