Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 11:9-28 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “Ninu àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ àwọn wọnyi: gbogbo ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, kì báà jẹ́ èyí tí ó ń gbé inú òkun tabi inú odò, ẹ lè jẹ wọ́n.

10. Ṣugbọn ohunkohun tí ó ń gbé inú òkun, tabi inú odò, ninu gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọn ń káàkiri inú omi, èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín.

11. Ohun ìríra ni wọn yóo jẹ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn, ohun ìríra ni òkú wọn gbọdọ̀ jẹ́ fun yín pẹlu.

12. Ohunkohun tí ó ń gbé inú omi, tí kò bá ti ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ohun ìríra ni fun yín.

13. “Àwọn wọnyi ni ẹ óo kà sí ohun ìríra, tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn ẹyẹ: idì, igún, ati oríṣìí àṣá kan tí ó dàbí idì,

14. gbogbo oniruuru àṣá,

15. gbogbo oniruuru ẹyẹ ìwò,

16. ògòǹgò, ati ẹyẹ kan bí ẹ̀lulùú tí ń gbé aṣálẹ̀,

17. ẹyẹ òwìwí, ẹyẹ òòyo, ati ẹyẹ kan bí igún,

18. ògbúgbú, òfú, ati àkàlà,

19. ẹyẹ àkọ̀, ati oniruuru yanjayanja, ẹyẹ atọ́ka, ati àdán.

20. “Gbogbo kòkòrò tí ó ní ìyẹ́, tí ó sì ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ìríra ni wọ́n jẹ́ fun yín.

21. Sibẹsibẹ ninu àwọn kòkòrò tí wọn ní ìyẹ́, tí wọn ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn, ẹ lè jẹ àwọn tí wọn bá ní tete tí wọ́n fi ń ta káàkiri lórí ilẹ̀.

22. Ẹ lè jẹ àwọn wọnyi ninu wọn: Oríṣìíríṣìí eṣú ati oríṣìíríṣìí ìrẹ̀ ati oríṣìíríṣìí tata.

23. Ṣugbọn gbogbo àwọn kòkòrò yòókù tí wọ́n ní ìyẹ́ tí wọ́n sì ní ẹsẹ̀ mẹrin, ìríra ni wọ́n jẹ́ fun yín.

24. “Àwọn ni wọ́n lè sọ yín di aláìmọ́; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

25. Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

26. Gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn bá là, ṣugbọn tí ẹsẹ̀ wọn kò là, tí wọn kì í sì í jẹ àpọ̀jẹ, aláìmọ́ ni wọ́n; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n di aláìmọ́.

27. Ninu àwọn ẹranko tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn tí wọ́n sì ní èékánná jẹ́ aláìmọ́ fun yín; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

28. Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; ohun àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fun yín.

Ka pipe ipin Lefitiku 11