Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 10:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọmọ Aaroni meji kan, ọkunrin, tí wọn ń jẹ́ Nadabu ati Abihu, mú àwo turari wọn, olukuluku fọn ẹ̀yinná sinu tirẹ̀, wọ́n da turari lé e lórí, wọ́n sì fi rúbọ níwájú OLUWA, ṣugbọn iná yìí kì í ṣe irú iná mímọ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wọn.

2. OLUWA bá rán iná kan jáde, iná náà jó wọn pa, wọ́n sì kú níwájú OLUWA.

3. Mose bá pe Aaroni, ó wí fún un pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘N óo fi ara mi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ láàrin àwọn tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ mi, n óo sì gba ògo níwájú gbogbo àwọn eniyan’ ” Aaroni dákẹ́, kò sọ̀rọ̀.

4. Mose bá pe Miṣaeli ati Elisafani, àwọn ọmọ Usieli, arakunrin Aaroni, ó ní, “Ẹ lọ gbé òkú àwọn arakunrin yín kúrò níwájú ibi mímọ́, kí ẹ sì gbé wọn jáde kúrò láàrin ibùdó.”

5. Wọ́n bá gbé wọn tẹ̀wù tẹ̀wù kúrò láàrin ibùdó gẹ́gẹ́ bí Mose ti wí.

6. Mose sọ fún Aaroni, ati àwọn ọmọ rẹ̀ meji, Eleasari ati Itamari pé, “Ẹ má ṣe fi irun yín sílẹ̀ játijàti, ẹ má sì ṣe fa aṣọ yín ya (láti fihàn pé ẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀), kí ẹ má baà kú, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí gbogbo eniyan. Ṣugbọn gbogbo ilé Israẹli, àwọn eniyan yín, lè ṣọ̀fọ̀ iná tí OLUWA fi jó yín.

7. Ẹ kò sì gbọdọ̀ jáde kúrò ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, kí ẹ má baà kú, nítorí pé òróró ìyàsímímọ́ OLUWA wà lórí yín.” Wọ́n sì ṣe bí Mose ti wí.

8. OLUWA bá Aaroni sọ̀rọ̀, ó ní,

9. “Nígbà tí o bá ń wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ, ìwọ, ati àwọn ọmọ rẹ, ẹ kò gbọdọ̀ mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ má baà kú; èyí yóo jẹ́ ìlànà títí ayé fún arọmọdọmọ yín.

10. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀, láàrin ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA ati ohun tí ó wà fún ìlò gbogbo eniyan; ẹ níláti mọ ìyàtọ̀, láàrin àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ mímọ́ ati àwọn ohun tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́;

11. ẹ sì níláti kọ́ àwọn eniyan Israẹli ní gbogbo ìlànà tí OLUWA ti là sílẹ̀, tí ó ní kí Mose sọ fun yín.”

12. Mose sọ fún Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tí wọ́n ṣẹ́kù, Eleasari ati Itamari, ó ní, “Ẹ gbé ohun ìrúbọ tí ó kù ninu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA, kí ẹ sì jẹ ẹ́ lẹ́bàá pẹpẹ, láì fi ìwúkàrà sí i, nítorí pé mímọ́ jùlọ ni.

Ka pipe ipin Lefitiku 10