Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 1:4-8 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ sísun náà, OLUWA yóo sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ.

5. Kí ó pa akọ mààlúù náà níbẹ̀, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá siwaju OLUWA, kí wọn da ẹ̀jẹ̀ náà yíká ara pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

6. Mú ẹran náà, kí o bó awọ rẹ̀, kí o sì gé e sí wẹ́wẹ́;

7. kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to igi sórí pẹpẹ náà kí wọ́n sì dáná sí i.

8. Lẹ́yìn náà, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to àwọn igẹ̀ ẹran náà ati orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ sórí igi tí wọ́n dáná sí, lórí pẹpẹ náà.

Ka pipe ipin Lefitiku 1