Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 1:4-10 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ sísun náà, OLUWA yóo sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ.

5. Kí ó pa akọ mààlúù náà níbẹ̀, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá siwaju OLUWA, kí wọn da ẹ̀jẹ̀ náà yíká ara pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

6. Mú ẹran náà, kí o bó awọ rẹ̀, kí o sì gé e sí wẹ́wẹ́;

7. kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to igi sórí pẹpẹ náà kí wọ́n sì dáná sí i.

8. Lẹ́yìn náà, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, to àwọn igẹ̀ ẹran náà ati orí rẹ̀ ati ọ̀rá rẹ̀ sórí igi tí wọ́n dáná sí, lórí pẹpẹ náà.

9. Ṣugbọn ẹni tí ó wá rúbọ yóo fi omi fọ àwọn nǹkan inú ẹran náà ati ẹsẹ̀ rẹ̀, alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ níná lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó jẹ́ ẹbọ olóòórùn dídùn sí OLUWA.

10. “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo aguntan tabi agbo ewúrẹ́ ni ó ti mú ẹran fún ẹbọ sísun rẹ̀, akọ tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú.

Ka pipe ipin Lefitiku 1