Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 1:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Kí ó pa á ní apá ìhà àríwá pẹpẹ níwájú OLUWA, kí àwọn ọmọ Aaroni, alufaa, da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yíká.

12. Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀, ati ọ̀rá rẹ̀, kí alufaa to gbogbo rẹ̀ sórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ.

13. Ṣugbọn kí ó fi omi fọ nǹkan inú rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀, kí alufaa fi gbogbo rẹ̀ rúbọ, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ náà. Ẹbọ sísun ni; ẹbọ tí a fi iná sun, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA dùn sí.

14. “Bí ó bá jẹ́ pé ẹyẹ ni eniyan bá fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, kí ó mú àdàbà tabi ọmọ ẹyẹlé wá.

15. Alufaa yóo gbà á, yóo fa ọrùn rẹ̀ tu, yóo sì sun ún lórí pẹpẹ, lẹ́yìn tí ó bá ti ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ tán;

16. kí ó fa àjẹsí rẹ̀ yọ, kí ó sì tu ìyẹ́ rẹ̀, kí ó dà á sí apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ náà, níbi tí wọn ń da eérú sí.

17. Kí ó fa apá rẹ̀ mejeeji ya, ṣugbọn kí ó má fà wọ́n já. Lẹ́yìn náà kí alufaa sun ún lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni, ẹbọ olóòórùn dídùn tí a fi iná sun sí OLUWA.

Ka pipe ipin Lefitiku 1