Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 1:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú Àgọ́ Àjọ ó ní,

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí ẹnikẹ́ni ninu yín bá fẹ́ mú ọrẹ ẹbọ wá fún èmi OLUWA, ninu agbo mààlúù, tabi agbo ewúrẹ́, tabi agbo aguntan rẹ̀ ni kí ó ti mú un.

3. “Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo mààlúù ni ó ti mú un láti fi rú ẹbọ sísun, akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú wá, kí ó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ, kí ó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA.

4. Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹbọ sísun náà, OLUWA yóo sì gbà á gẹ́gẹ́ bí ẹbọ láti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ.

Ka pipe ipin Lefitiku 1