Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 9:29-40 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Iṣẹ́ àwọn mìíràn ninu wọn ni láti máa tọ́jú ohun ọ̀ṣọ́ tẹmpili ati ohun èlò mímọ́, ati ìyẹ̀fun ọkà, waini, òróró, turari, ati òjíá.

30. Àwọn ọmọ alufaa yòókù ni wọ́n ń po turari,

31. Matitaya, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi tí ó jẹ́ àkọ́bí Ṣalumu ará Kora níí máa ń ṣe àkàrà ìrúbọ.

32. Bákan náà, àwọn kan ninu àwọn ọmọ Kohati, ni wọ́n máa ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn ní ọjọọjọ́ ìsinmi.

33. Àwọn ọmọ Lefi kan wà fún orin kíkọ ninu tẹmpili, wọ́n jẹ́ baálé baálé ninu ẹ̀yà Lefi, ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu tẹmpili ni àwọn ń gbé, wọn kì í bá àwọn yòókù ṣiṣẹ́ mìíràn ninu tẹmpili, nítorí pé iṣẹ́ tiwọn ni orin kíkọ tọ̀sán-tòru.

34. Baálé baálé ni àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi ninu ìdílé wọn, olórí ni wọ́n ninu ẹ̀yà Lefi, wọ́n ń gbé Jerusalẹmu.

35. Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ìlú Gibeoni, iyawo rẹ̀ ń jẹ́ Maaka,

36. Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, Neri, ati Nadabu;

37. Gedori, Ahio, Sakaraya, ati Mikilotu;

38. Mikilotu bí Ṣimea; àwọn náà ń gbé lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọn ni òdìkejì ibùgbé àwọn arakunrin wọn ní Jerusalẹmu.

39. Neri ni ó bí Kiṣi, Kiṣi bí Saulu, Saulu ni baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali.

40. Jonatani ni ó bí Meribibaali; Meribibaali sì bí Mika.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 9