Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 9:25-33 BIBELI MIMỌ (BM)

25. àwọn eniyan wọn tí wọn ń gbé àwọn ìletò a máa wá ní ọjọ́ meje meje, láti ìgbà dé ìgbà, láti wà pẹlu àwọn olórí ọ̀gá aṣọ́nà mẹrin náà.

26. Nítorí àwọn olórí mẹrin wọnyi, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, ni wọ́n tún ń ṣe alabojuto àwọn yàrá tẹmpili ati àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé Ọlọrun.

27. Wọ́n ń gbé àyíká ilé Ọlọrun, nítorí iṣẹ́ wọn ni láti máa bojútó o, ati láti máa ṣí ìlẹ̀kùn rẹ̀ ní àràárọ̀.

28. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi ni alabojuto àwọn ohun èlò ìjọ́sìn, iṣẹ́ wọn ni láti máa fún àwọn tí wọ́n ń lò wọ́n, ati láti gbà wọ́n pada sí ipò wọn, kí wọ́n sì kà wọ́n kí wọ́n rí i pé wọ́n pé.

29. Iṣẹ́ àwọn mìíràn ninu wọn ni láti máa tọ́jú ohun ọ̀ṣọ́ tẹmpili ati ohun èlò mímọ́, ati ìyẹ̀fun ọkà, waini, òróró, turari, ati òjíá.

30. Àwọn ọmọ alufaa yòókù ni wọ́n ń po turari,

31. Matitaya, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi tí ó jẹ́ àkọ́bí Ṣalumu ará Kora níí máa ń ṣe àkàrà ìrúbọ.

32. Bákan náà, àwọn kan ninu àwọn ọmọ Kohati, ni wọ́n máa ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn ní ọjọọjọ́ ìsinmi.

33. Àwọn ọmọ Lefi kan wà fún orin kíkọ ninu tẹmpili, wọ́n jẹ́ baálé baálé ninu ẹ̀yà Lefi, ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu tẹmpili ni àwọn ń gbé, wọn kì í bá àwọn yòókù ṣiṣẹ́ mìíràn ninu tẹmpili, nítorí pé iṣẹ́ tiwọn ni orin kíkọ tọ̀sán-tòru.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 9