Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 8:32-40 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Mikilotu (baba Ṣimea). Wọ́n ń bá àwọn arakunrin wọn gbé, àdúgbò wọn kọjú sí ara wọn ní Jerusalẹmu.

33. Neri ni baba Kiṣi, Kiṣi ni ó bí Saulu, Saulu sì bí àwọn ọmọkunrin mẹrin: Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali.

34. Jonatani bí Meribibaali, Meribibaali sì bí Mika.

35. Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi.

36. Ahasi ni baba Jehoada. Jehoada sì ni baba: Alemeti, Asimafeti, ati Simiri. Simiri ni ó bí Mosa.

37. Mosa bí Binea; Binea bí Rafa, Rafa bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli.

38. Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani. Aseli ni baba gbogbo wọn.

39. Eṣeki, arakunrin Aseli, bí ọmọ mẹta: Ulamu ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà Jeuṣi, lẹ́yìn náà Elifeleti.

40. Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ jagunjagun, tafàtafà ni wọ́n, wọ́n sì lókìkí. Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ̀ pọ̀. Aadọjọ ni wọ́n, ara ẹ̀yà Bẹnjamini sì ni gbogbo wọ́n.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 8