Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 8:30-39 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, ati Nadabu;

31. Gedori, Ahio, Sekeri, ati

32. Mikilotu (baba Ṣimea). Wọ́n ń bá àwọn arakunrin wọn gbé, àdúgbò wọn kọjú sí ara wọn ní Jerusalẹmu.

33. Neri ni baba Kiṣi, Kiṣi ni ó bí Saulu, Saulu sì bí àwọn ọmọkunrin mẹrin: Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu, ati Eṣibaali.

34. Jonatani bí Meribibaali, Meribibaali sì bí Mika.

35. Mika bí ọmọkunrin mẹrin: Pitoni, Meleki, Tarea ati Ahasi.

36. Ahasi ni baba Jehoada. Jehoada sì ni baba: Alemeti, Asimafeti, ati Simiri. Simiri ni ó bí Mosa.

37. Mosa bí Binea; Binea bí Rafa, Rafa bí Eleasa, Eleasa sì bí Aseli.

38. Aseli bí ọmọkunrin mẹfa: Asirikamu, Bokeru, Iṣimaeli, Ṣearaya, Ọbadaya, ati Hanani. Aseli ni baba gbogbo wọn.

39. Eṣeki, arakunrin Aseli, bí ọmọ mẹta: Ulamu ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà Jeuṣi, lẹ́yìn náà Elifeleti.

Ka pipe ipin Kronika Kinni 8