Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 7:30-40 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Àwọn ọmọ Aṣeri nìwọ̀nyí: Imina, Iṣifa, Iṣifi ati Beraya, ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Sera.

31. Beraya bí ọmọkunrin meji: Heberi ati Malikieli, baba Birisaiti.

32. Heberi bí ọmọkunrin mẹta: Jafileti, Ṣomeri ati Hotamu; ati ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Ṣua.

33. Jafileti bí ọmọ mẹta: Pasaki, Bimihali, ati Aṣifatu.

34. Ṣomeri, arakunrin Jafileti, bí ọmọkunrin mẹta: Roga, Jehuba ati Aramu.

35. Hotamu, arakunrin rẹ̀, bí ọmọkunrin mẹrin: Sofa, Imina, Ṣeleṣi ati Amali.

36. Sofa bí Ṣua, Haneferi, ati Ṣuali; Beri, ati Imira;

37. Beseri, Hodi, ati Ṣama, Ṣiliṣa, Itirani, ati Beera.

38. Jeteri bí: Jefune, Pisipa, ati Ara.

39. Ula bí: Ara, Hanieli ati Risia.

40. Àwọn ni ìran Aṣeri, wọ́n jẹ́ baálé baálé ni ìdílé baba wọn, àṣàyàn akọni jagunjagun, ati olórí láàrin àwọn ìjòyè. Àkọsílẹ̀ iye àwọn tí wọ́n tó ogun jà ninu wọn, ní ìdílé ìdílé jẹ́ ẹgbaa mẹtala (26,000).

Ka pipe ipin Kronika Kinni 7