Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Kinni 3:4-13 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ní Heburoni, níbi tí Dafidi ti jọba fún ọdún meje ati ààbọ̀, ni wọ́n ti bí àwọn mẹfẹẹfa fún un.Lẹ́yìn náà, Dafidi jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹtalelọgbọn.

5. Àwọn ọmọ tí Dafidi bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí:Batiṣeba, ọmọbinrin Amieli, bí ọmọ mẹrin fún un: Ṣimea, Ṣobabu, Natani ati Solomoni.

6. Àwọn ọmọ mẹsan-an mìíràn tí Dafidi tún bí ni: Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti;

7. Noga, Nefegi, ati Jafia,

8. Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti,

9. Dafidi ni ó bí gbogbo wọn, yàtọ̀ sí àwọn ọmọ tí àwọn obinrin mìíràn tún bí fún un. Ó bí ọmọbinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tamari.

10. Àwọn ọmọ Solomoni ọba nìwọ̀nyí: Rehoboamu, Abija, Asa, ati Jehoṣafati;

11. Joramu, Ahasaya, ati Joaṣi;

12. Amasaya, Asaraya, ati Jotamu;

13. Ahasi, Hesekaya, ati Manase,

Ka pipe ipin Kronika Kinni 3